HYMN 588

H.C 353 12s (FE 614)
“Emi mbo nisisiyi ere mi si mbe pelu
mi, lati fun olukuluku enia gegebi ise 
re yio ti ri” - Ifi. 22:121. AO sise! ao sise! om' 

   Olorun ni wa

   Jek'a tele ipa ti Oluwa wa to

   K‘a f’ imoran

   Re so agbara wa d‘otun 

   K’a fi gbogbo okun wa

   sise t’a o se.

Egbe: Foriti! Foriti!

      Ma reti, ma sona 

      Titi Oluwa o fi de.


2. Ao sise! ao sise!, bo awon t’ebi npa 

   Ko awon alare lo s‘orisun iye! 

   Ninu agbelebu l'awa o ma sogo 

   Gbati a ba nkede pe, ‘Ofe n‘Igbala.

Egbe: Foriti! Foriti!...


3. Ao sise, ao sise! gbogbo wa ni y’o se 

   Ijoba okunkun at‘iro yo fo

   Ao si gbe oruko Jesu leke

  N’nu orin iyin wa pe, ‘Ofe n’Igbala.

Egbe: Foriti! Foriti!...


4. Ao sise! ao sise! l‘agbara Oluwa, 

   Agbala at'ade y’o si je ere wa 

  Gbat’ ile awon oloto ba di tiwa

  Gbogbo wa o jo ho pe 

  ‘Ofe n'Igbala.

Egbe: Foriti, foriti

      Ma reti, ma sona 

      Titi Oluwa o fi de. Amin

English »

Update Hymn