HYMN 589

C.M.S 390 H.C 349. 6.6s (FE 615)
"Nwon fi awon tikara won fun Oluwa"
- 2Kor.8:5 
1. MO fara mi fun O

   Mo ku nitori re

   Ki nle ra o pada 

   K’o le jinde nn'oku 

   Mo f 'ara mi fun o 

   Kini ‘wo se fun Mi?


2. Mo f’ojo aiye Mi 

   Se wahala fun o 

   Ki iwo ba le mo 

   Adun aiyeraiye

   Mo lo p'odun fun o 

   O lo kan fun Mi bi?


3. Ile ti Baba Mi 

   At‘ite ogo Mi

   Mo fi sile w’aiye 

   Mo d' alarinkiri 

   Mo fi ‘le tori re 

   Kil’ o f'ile fun Mi?


4. Mo jiya po fun o 

   Ti enu ko le so 

   Mo jijakadi nla 

   Tori igbala re 

   Mo jiya po fun o 

   O le jiya fun mi?


5. Mo mu igbala nla 

   Lat’ile baba mi 

   Wa, lati fi fun o 

   Ati idariji

   Mo m’ebun wa fun o 

   Kil'o mu wa fun Mi?


6. Fi ara re fun mi

   Fi aiye re sin Mi 

   Di ju si nkan t’aiye 

   Si wo ohun t'orun 

   Mo f‘ara Mi fun o 

   Si f'ara re fun Mi? Amin

English »

Update Hymn