HYMN 591

H.C 346 5.6s (FE 617)
"Emi o si pelu re, Emi o si ko
o li eyiti iwo o wi" - Eks.4:121. TAN ‘mole Re si wa

   Loni yi Oluwa

   Fi ara Re han wa 

   N’nu oro Mimo Re 

   Jo m’okan wa gbona 

   K'a ma wo oju Re 

   K’awon ‘mode le ko 

   lyanu ore Re.


2. Mi si wa Oluwa 

   lna Emi Mimo 

   K‘a le fi okan kan
 
   Gbe oruko Re ga 

   Jo fi eti igbo 

   At’okan ironu 

   Fun awon ti a nko 

   L’ohun nla t’O ti se.


3. Ba ni so, Oluwa 

   Ohun to ye k’a so 

   Gege bi oro Re

   Ni ki eko wa je 

   K’awon agutan Re 

   Le ma mo ohun Re 

   lbit’ O nto won si 

   Ki nwon si le ma yo.


4. Gbe ‘nu wa Oluwa

   K'ife Re je tiwa

   lwo nikan lao fi

   lpa wa gbogbo sin

   K’iwa wa je eko

   Fun awon omo Re

   K’o si ma kede Re

   Ninu gbogbo okan. Amin

English »

Update Hymn