HYMN 595

H.C 346 S.M (FE 621)
“Alabukun fun ni enyin ti 
nfurugbin nihan omi gbogbo”
 - Isa. 32:201. FUNRUGBIN lowuro 

   Ma simi tit'ale 

   F’eru on ‘yemeji sile 

   Ma fun sibi gbogbo.


2. Wo ko mo‘yi ti nhu 

   T'oro tabi t‘ale 

   Ore-ofe yio pa mo 

   Bit‘o wu k‘o bo si.


3. Yio si hu jade

   L'ewu tutu yoyo

   Beni y’o si dagba soke 

   Y'o s’eso nikehin.


4. Wo k’y’o sise lasan 

   Ojo, iri orun

   Yio jumo jo sise po 

   Fun ikore orun.


5. Nje nikehin ojo

   Nigbat’ opin ba de

   Awon Angeli’ y’o si wa ko 

   lkore lo sile. Amin

English »

Update Hymn