HYMN 596

L.M (FE 622)
“Oru mbo wa nigbati enikan ki 
o le sise" - Joh. 9:41. MA sise lo mase sole

   Enyin Omo Egbe Serafu 

   Ikore po, ko s’agbase 

   Gbogbpo wa ni yio gb’ere na.


2. Ma sise lo, mase sole 

   Enyin Omo Egbe Kerubu 

   E jade lo s’opopo aiye 

   Gbogbo wa ni yio gb’ere na.


3. Ma sise lo, mase sole 

   Ma jeki fitila nyin ku

   Omo ‘ya wa ni ebi npa 

   Gbogbo wa ni yio gb’ere na.


4. Ma sise lo, mase sole

   Mase wo awon elegan

   K’a fi keta gbogbo sile 

   Gbogbo wa ni yio gb’ere na.


5. Ma sise lo, mase sole

   Awa yio korin Halleluya 

  Orin Halle, Halleluyah 

  Nigbat‘ a ba r’Olugbala 

  Amin, Amin,. Ase. Amin

English »

Update Hymn