HYMN 597

(FE 623)
Tune: Eyin Omo Egbe Kerubu 1. JEHOVAH Rufi Baba wa 

   Fun wa l’okan okun ilera 

   Ki a le jo f’iyin fun Baba 

   Gege bi awon t’orun.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu (2) 

     Ipe na ndun, ronupiwada 

     A! e wa k'a sin Jesu.


2. Gbogbo aiye, e yin Jesu 

   Ohun rere d’ode

   E f’iyin fun Baba l’oke 

   T’o d’Egbe yi sile.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


3. Gbogbo onigbagbo Ijo 

   Orun ododo d’ode 

   Olorun npe nsisiyi

   E jek’a gbo ipe Re.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


4. Jehovah Nissi Baba wa 

   Jek'a le je tire 

   Emi Mimo ‘Daba orun 

   Jowo to wa s’ona.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


5. Ma banuje, ma b’ohun bo 

   Ninu Egbe Serafu 

   Olupese, Olugbala

   Ki yio fi o sile.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


6. Enyin Angeli mererin 

   T’e gbe aiye dani 

   E jowo ma f'aiye sile O

   E ma wo ‘ wa eda.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


7. Maikeli mimo pelu ida Re 

   Ngesin fo yi wa ka 

   Kerubu pelu ogun re

   La ‘ju awon ariran.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


8. A! ojo nla, ojo dajo

   Ma jek’oju ti wa

   T’oju gbogbo aiye yio pe 

   Lodo Baba l’oke.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


9. Jesu masai ran wa lowo 

   Mase fi wa sile

   Gbati danwo ba yi wa ka 

   Jesu gbe wa leke.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


10. Ko s’ore t’o dabi Jesu 

    Ko s‘eni mba kepe

    Mo wo waju mo wo ehin 

    Alabaro ko si.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


11. Ranti pe o ti ko esu 

    Ati gbogbo ise re 

    Egun ni fun o bi o tun 

    Pada sodo Esu.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu...


12. Ogo ni fun Baba l’oke 

    Ogo ni f’Omo Re 

    Ogo ni fun Emi Mimo

    Metalokan lailai.

Egbe: A! e wa k’a sin Jesu (2) 

     Ipe na ndun, ronupiwada 

     A! e wa k'a sin Jesu. Amin

English »

Update Hymn