HYMN 598

C.M.S 389 S.492 P.M (FE 624)
“Eniti o ba fori ti titi de opin, on 
li a o gbala” - Matt.24:131. OKAN are ile kan mbe 

   Lona jinjin s’aiye ise 

   Ile t’ayida ko le de 

   Tani ko fe simi nibe.

Egbe: Dur‐roju duro mase kun! (2ce)

     Duro, duro, sa roju duro

     mase kun.


2. Bi wahala bo o mole 

   B’ipin re laiye ba buru 

   W’o oke s’ile ibukun na 

   Sa roju, duro mase kun. 

Egbe: Duro...


3. Bi egun ba wa lona re 

   Ranti ori t’a f ’egun de 

   Bi ‘banuje bo okan re 

   O ti ri be f’Olugbala. 

Egbe: Duro...


4. Ma sise lo, mase ro pe 

   A ko gbadura edun re 

   Ojo isimi mbo kankan 

   Sa roju duro, mase kun.

Egbe: Dur‐roju duro mase kun! (2ce)

     Duro, duro, sa roju duro

     mase kun. Amin

English »

Update Hymn