HYMN 6

C.M.S 4, H.C. 16, L.M (FE 23)
“Ma rin niwaju mi, ki iwo si pe"
 - Gen. 17:1


1. OLUWA mi, mo njade lo,

   Lati seise ojo mi, 

   lwo nikan l'emi o mo,

   L'oro l’ero, ati n'ise.


2. Ise t’o yan mi l'anu Re 

   Jeki nle se tayo tayo

   Ki nroju Re ni ise mi 

   K‘emi si le f’ife Re han.


3. Dabobo mi mi lowo ‘danwo 

   K ' o pa okan mi mo kuro, 

   L'owo aniyan aiye yi,

   Ati gbogbo ifekufe.


4. lwo t'oju Re r’okan mi, 

   Ma wa low'otun mi titi

   Ki mma sise lo lase Re,

   Ki nf'ise mi gbogbo fun O.


5. Je ki nr'eru Re t'o fuye

   Ki mma sora nigbagbogbo; 

   Ki mma f'oju si nkan t‘orun 

   Ki nsi mura d‘ojo ogo.


6. Ohunkohun t'o fi fun mi,

   Jeki nle lo fun ago Re,

   Ki nf'ayo sure ije mi,

   Ki mba O rin titi d'orun. Amin

English »

Update Hymn