HYMN 604

C.M.S 406 t. H.C 18 C.M (FE 630)
'Gbogbo eniti ongbe ngbe, e wa sibi 
omi" - Isa. 55:11. ENYIN t’ongbe ngbe e wa mu

   Omi iye ti nsan

   Lati orisun ti Jesu

   Lai sanwo l’awa mbu.


2. Wo! b’o ti pe to t'e ti nmu

   Ninu nkan eke

   T'e nl'agbara at’ogun nyin

   Ninu nkan t'o nsegbe.


3. Jesu wipe, isura mi

   Ko lopin titi lai

   Yio f ‘ilera lailai fun

   Awon t'o gbo Tire. Amin

English »

Update Hymn