HYMN 608

C.M.S 404 t. S. 675 D. 85 (FE 634)
“Nibo ni iwo wa" - Gen. 3:91. NlGBAT’ idanwo yi mi ka 

   Ti idamu aiye mu mi 

   T‘ota fara han bi ore

   Lati wa iparun fim mi.

Egbe: OIuwa, jo ma sai pe mi 

     B’o ti pe Adam nin'ogba 

     Pe’ Nibo I’o wa elese?

     Ki nIe bo ninu ebi na.


2. Nigbat’Esu n’nu ‘tanje re 

   Gbe mi gori oke aiye

   T’o ni ki nteriba fun on 

   K'ohun aiye le je temi

Egbe: OIuwa jo...


3. Gbat' ogo aiye ba fe fi 

   Tulasi mu mi rufin Re 

   To duro gangan lehin mi 

   Ni ileri pe’Ko si nkan.

Egbe: OIuwa jo...


4. Nigbati igbekele mi 

   Di t’ogun ati t’orisa 

   T’ogede di adura mi 

   Ti ofo di ajisa mi.

Egbe: OIuwa jo...


5. Nigbati mo fe lati rin 

   L’adamo at’ife n’nu mi 

   T’okan mi nse hila-hilo 

   Ti nko gbona, ti nko tutu. 

Egbe: OIuwa jo...


6. Nigba mo sonu bi aja 

   Laigbo ifere ode mo 

   Ti nko nireti ipada

   Ti mo npafo ninu ese.

Egbe: OIuwa jo...


7. Nigbati ko s’alabaro

   Ti Olutunu si jina

   T’ibanuje b’iji lile

   Te ori mi ba n’ironu.

Egbe: OIuwa, jo ma sai pe mi 

     B’o ti pe Adam nin'ogba 

     Pe’ Nibo I’o wa elese?

     Ki nIe bo ninu ebi na. Amin

English »

Update Hymn