HYMN 609

C.M.S 73 H.C 65 2nd Ed 8.7.4 (FE 635)
“Wakati mbo ninu eyiti gbogbo awon ti
o wa ni isa oku yio gbo ohun re, nwon 
o si jade wa” - John 5:28
1. OJO ‘dajo ojo eru! 

   Gbo bi ipe ti ndun to! 

   Oju egberun ara lo 

   O si nmi gbogbo aiye 

   Bi esun na

   Y’o ti damu elese.


2. Wo Onidajo l’awo wa

   T'o wo ogo nla l‘aso 

   Gbogbo nwon ti nwo ona Re 

   Gbana ni nwon o ma yo

   Olugbala

   Jewo mi ni ojo na.


3. Ni pipe Re oku o ji 

   Lat' okun, ile s’iye

   Gbogbo ipa aiye y’o mi 

   Nwon o salo loju Re 

   Alaironu

   Yio ha ti ri fun o?


4. Esu ti ntan o nisiyi 

   Iwo mase gbo tire 

   Gbati aiye yi ba koja 

   Y’o ri o ninu ina 

   Iwo ronu

   Ipo re ninu ina.


5. Labe iponju at‘egun 

   K’eyi gba o n’ iyanju 

   Ojo Olorun mbo tete 

   'Gbana ekun y’o d’ayo 

   A o segun

   Gbati aiye ba gbina. Amin


English »

Update Hymn