HYMN 612

(FE 638)1. OHUN aiye b’aiye lo 

   Kerubu, Serafu

   Ilu ti a te sori oke

   A ko le fara sin.

Egbe: Je ka soto - (3) 

      Ka le ri gbala 

      nikehin.


2. Ohun aiye b’aiye lo 

   E ranti ti aya Loti 

   Ti o boju wo ehin 

   Ti o fi di owon iyo.

Egbe: Je ka soto...


3. Ohun aiye b’aiye lo 

   E ranti ojo Mose

   Ti Farao fi ri s’okun 

   Ti Israel fi ri igbala.

Egbe: Je ka soto...


4. Ohun aiye b’aiye lo 

   E ranti ojo Noah 

   T’omo enia fi npegan 

   Ti eranko fi ri igbala.

Egbe: Je ka soto...


5. Enyin Egbe Oloye 

   At’enyin egbe Mary 

   Baba yio wa pelu nyin 

   Yio di nyin lamure ododo.

Egbe: Je ka soto...


6. Enyin Egbe Martha 

   Ati Ayaba Esther

   E mura lati sise nyin 

   Baba yio se iranwo.

Egbe: Je ka soto...


7. Enyin Egbe Akorin 

   Ati ‘Tan-lehin Jesu 

   E mura lati sise nyin 

   Jesu yio se iranwo.

Egbe: Je ka soto...


8. Mose Orimolade

   O ti lo soke orun

   O dapo mo awon Angel 

   O ti gbade Ogo.

Egbe: Je ka soto...


9. Enyin Egb’Aladura

   E ku aseyinde

   Baba yio tu nyin ninu 

   Yio gb’owo nyin soke.

Egbe: Je ka soto...


10. Ogo ni fun Baba wa 

    Ogo ni fun Omo Re 

    Ogo ni fun Emi Mimo 

    Metalokan lailai.

Egbe: Je ka soto - (3) 

      Ka le ri gbala 

      nikehin. Amin

English »

Update Hymn