HYMN 615

S.S 366 (FE 641)
“A ko le ma sai tun nhyin bi” 
- John 3:71. IJOYE kan to Jesu lo l'oru

   O mbere ona ‘mole on igbala 

   Olukoni f‘esi to yanju pe

   Ki a sa tun yin bi.

Egbe: Ki a sa tun yin bi - 2ce

      Lotito, lotito ni mo wi fun o 

      Ki a sa tun nyin bi.


2. Enyin om’araiye sami soro na 

   Ti Jesu Oluwa fara bale so 

   Mase jek‘iko yi si o j’asan

   Ki a sa tun nyin bi.

Egbe: Ki a sa tun yin bi...


3. Enyin to fe wo ‘simi to l’ogo yi 

   Te nfe b'enirapada korin bukun 

   Bi e ba nfe gba iye ainipekun

   Ki a sa tun nyin bi. 

Egbe: Ki a sa tun yin bi...


4. O nfe r‘olufe kan t’o ti lo bi? 

   Lenu lekun dada to ti nsona fun o

   Nje teti s'egbe orin didun yi pe

   Ki a sa tun nyin bi.

Egbe: Ki a sa tun yin bi - 2ce

      Lotito, lotito ni mo wi fun o 

      Ki a sa tun nyin bi. Amin

English »

Update Hymn