HYMN 624

(FE 650)
“Mo gb’ohun Re" - Gen. 3:101. MO gb'ohun Re ninu ala mi 

   Ohun kelekele

   Ohun ti nso ‘fe t’Oluwa

   Ife irapada

   Mo te’ti lele lati gbo 

   O si ya mi lenu. 

   Jo jeki nroju Re. 

Egbe: Jo jeki nroju Re - 2ce 

      Bi mo ti te ‘ti le le to 

      Jo jeki nroju re.


2. Ninu wahala aiye mi 

   Mo ba Jesu pade

   Ti O si gba mi niyanju 

   Lati ma gbadura

   Mo te’ti le le lati gbo

   O si mu ‘nu mi dun

   O si tun ki mi l’aiya pe 

   Ki nsa ma gba adura.

Egbe: Ki nsa ma gba 'dura - 2ce 

      O si tun ki ni I‘aya pe 

      Ki nsa ma gba adura.


3. Olodumare jo gba wa 

   Awa Egbe Serafu 
 
   Nigbati wahala ba de 

  Jo gbo adura wa

  Ran awon Kerubu si wa 

  Lati ran wa lowo

  Ki O si te ‘ti si igbe wa 

  K’O gbo adura wa.

Egbe: K'O gbo adura wa - 2ce

      Ki O si te 'ti si igbe wa 

      K’O gbo adura wa. Amin

English »

Update Hymn