HYMN 626

11s (FE 652)
"Awon ti o gbekele Oluwa yio dabi 
Oke Sioni ti a ko le si ni di" - Ps.125:1
Tune: E ma tesi waju Serafu Mimo1. NI INU airiji re gbekele Jesu

   Ni inu hila-hilo aiye, gbekele Jesu 

   Mase gbekele enia, sugbon gbekele Jesu, 

   On nikan lo le gba o, sa gbeke re le.

Egbe: Enit’ o npese fun era 

      On na ko le bo o ti 

      Bi o ti wu k'o le to

      Gbekele Jesu.


2. Enyin Om'Ogun ‘gbala yi gbekele Jesu 

   E ke Hosanna f’Oba omo ninu Dafidi 

   Enit’O ni kokoro iku ati iye lowo 

   On nikan lo le gba o sa ma se ‘fe Re.

Egbe: Enit’ o npese fun era...


3. Enyin Leader wa owon, E ku se Emi 

   Jah yio so ile ati ona nyin, 

   Sa ma s’otito

   Jeki iwa rere nyin han

   Fun gbogbo awon eda 

   Ogun orun yio jeri nyin 

   enyin o gb’ade ade ogo.

Egbe: Enit’ o npese fun era...


4. Enyin Egbe Aladura 

   e ma bohun mo

   Sise nigbati nse osan 

   nitori oru mbo

   Gbe ida ‘segun re s'oke, e

   mase b’oju w‘ehin

   Ma gbeke re le enia, teju mo Iesu.

Egbe: Enit’ o npese fun era...


5. Enyin omo Egbe Akorin

   E tun ohun nyin se

   Orin l'e o ma ko titi n‘ile 

   Baba orun 

   Jesu yio mu nyin de’le lo si 

   ilu mimo l’oke

   Lati pelu ogun orun ti 

   nyins Od’agutan.

Egbe: Enit’ o npese fun era...


6. Enyin Om’Egbe Serafu ati Kerubu 

   Emi Mimo yio ma so nyin ma 

   beru ota

   Agbara tit’ oke wa orin

   segun l’ ao ma ko,

   Ogo fun Baba, Omo ati Emi Mimo.

Egbe: Enit’ o npese fun era 

      On na ko le bo o ti 

      Bi o ti wu k'o le to

      Gbekele Jesu. Amin

English »

Update Hymn