HYMN 627

H.C 509 P.M (FE 653)
“Okan mi nto O lehin girigiri”
- Ps. 63:81. L’EKAN mo jina s’Oluwa 

   Mo nfi iwa mi bi ninu 

   Sugbon Jesu ti gba mi, 

   Halleluya.


Chorus: A, bi o ti dun to

       Dun to, dun to dun to 

       A, bi o ti dun to

       Ki Jesu ma gbe inu mi.


2. Ibinu ati runu mi

   Ewon ti Esu fi de mi

   Jesu ti da ide na 

   Halleluya.

Chorus: A, bi o ti dun to, - 3ce...


3. Ifekufe kun okan mi

   Pelu igberaga gbogbo 

   In’Emi ti jo won

   Halleluya.

Chorus: A!, bi o ti dun to, - 3ce...


4. Mo bo lowo irewesi, 

   Lowo ko gbona ko tutu, 

   E ba mi yin Oluwa 

   Halleluya.

Chorus: A!, bi o ti dun to, - 3ce...


5. Mo nkorin si lojojumo

   Mo nyo mo si tun nfo s’oke

   Nipa gbara Emi

   Halleluya.

Chorus: A!, bi o ti dun to, - 3ce...


6. Eje yebiye we mi mo 

   Omi iye nsan ninu mi

   Igbala mi di kikun

   Halleluya.

Chorus: A!, bi o ti dun to, - 3ce...


7. Enyin ara at’ore mi 

   Tani ko fe ri igbala

   Ofe ni l’odo Jesu

   Halleluya.

Chorus: A, bi o ti dun to

       Dun to, dun to dun to 

       A, bi o ti dun to

       Ki Jesu ma gbe inu mi. Amin

English »

Update Hymn