HYMN 628

(FE 654) DCM
“Igbala mi mbe li owo Re" - Ps.31:151. IGBA mi mbe li owo re 

   Jesu Olugbala

   Gbogb’ aniyan at’ero mi 

   Ni mo fi ro s’odo Re.

Egbe: Sanu fun mi, gb'adura mi

      Ran mi lowo

      Sanu fun mi, gb'adura mi

      Ran mi lowo

      Iwo ni mo gbekele.


2. lgba mi mbe li owo Re 

   Ko si ‘foiya fun mi mo 

   Baba ki yio je k’omo Re 

   Sokun ni ainidi. 

Egbe: Sanu fun mi...


3. Tani yio gbe Jakobu dide 

   Ni ero araiye 
 
   Egun gbigbe tun le soji 

   Lagbara Oga Ogo. 

Egbe: Sanu fun mi...


4. B‘aiye tile d‘oju ko mi 

   Ti ota nlepa mi

   Sibe b'O ba wa pelu mi 

   Kini yio fo mi l’aiya. 

Egbe: Sanu fun mi...


5. Bi ko tile s'alabaro 

   Ti Olutunu jina 

   Olorun yio bo asiri 

   F’enit’o ba gbeke E. 

Egbe: Sanu fun mi...


6. Apata mi aiyeraiye

   Wo ni mo gbekle

   Jowo ma jek’Oju ti mi 

   Ttti ngo fi d'odo re.

Egbe: Sanu fun mi, gb'adura mi

      Ran mi lowo

      Sanu fun mi, gb'adura mi

      Ran mi lowo

      Iwo ni mo gbekele. Amen

English »

Update Hymn