HYMN 631

C.M.S 498 H.C 516 7s (FE 657) 
"Bi enikeni ba nsin, mi ki o ma to
Mi lehin” - John 12:26 1. MO ti seleri Jesu

   Lati sin O dopin 

   Ma wa lodo mi titi 

   Baba mi, Ore mi

   Emi k’yo beru ogun 

   B’lwo ba sunmo mi 

   Emi ki y'o si sina 

   B’O ba f’ona han mi.


2. Je ki nmo p’O sunmo mi 

   Tori ibaje aiye

   Aiye fe gba okan mi 

   Aiye fe tan mi je 

   Ota yi mi ka kiri

   Lode ati ninu

   Sugbon Jesu, sunmon mi 

   Dabobo okan mi.


3. Je ki emi k’o ma gbo 

   Ohun Re, Jesu mi 

   Ninu igbi aiye yi

   Titi nigbagbogbo 

   Ko, mu k’o dami l’oju 

   K’okan mi ni janu

   Ko, si mu mi gboTire 

   Wo Olutoju mi.


4. Wo ti seleri, Jesu 

   F’awon t’o tele O 

   Pe ibikibi ti O wa 

   L’awon yio si wa 

   Mo ti seleri, Jesu 

   Latin sin O dopin 

   Jeki nma to O lehin 

   Baba mi, Ore mi.


5. Jeki nma ri pase Re 

   Ki nle ma tele O 

   Agbara Re nikan ni

   Ti mba le tele O 

   To mi, pe mi, si fa mi

   Di mi mu de opin

   Si gba mi si odo Re 

   Baba mi, Ore mi. Amin

English »

Update Hymn