HYMN 632

C.M.S 497 t.H.C 324 8s 7s. (FE 658)
"Wa sodo mi" - Isa. 55:31. EMI o lo sodo Jesu 

   Eni npe mi pe ki nwa 

   Enit’ o se Olugbala 

   Fun elese bi emi.


2. Emi o lo sodo Jesu 

   Irira at’ibinu

   Ika at'ise t'o buru 

   T’enia nse, On ko ni.


3. Emi o lo sodo Jesu 

   O dun mo mi ki nse be 

   Tal’ o fe mi bi ti Jesu 

   Eniti o gba ni la?


4. Emi o lo sodo Jesu 

   Jesu t'o se Ore wa

   Anu wa ninu Re pupo 

   Fun elese bi emi. Amin

English »

Update Hymn