HYMN 635

C.M.S 475 H.C 411 2nd Ed. H.C 470 
6s, 8s (FE 661)
“Ma wi, nitori omo-odo Re ngbo" - 1Sam.3:91. GBATI Samueli ji 

   T'o gb’ohun Eleda

   Ni gbolohun kokan 

   Ayo re ti po to

   Ibukun ni f’omo t‘o ri 

   Olorun nitosi re be.


2. B'Olorun ba pe mi 

   Pe, ore mi li On

   Ayo mi y'o ti to 

   Ngo si f’eti sile

   Ngo sa f’ese t‘o kere ju 

   B’Olorun sunmo ‘tosi be.


3. Ko ha mba ni soro? 

   Beni, n'nu Oro Re 

   O npe mi lati wa 

   Olorun Samueli

   N'nu lwe na ni mo ka pe 

   Olorun Samuel npe mi.


4. Mo le f’ori pamo 

   S’abe itoju Re

   Mo mo p’Olorun mbe 

   Lodo mi n'gbagbogbo

   O ye k’eru ese ba mi 

   Tor’ Olorun sunmo 'tosi.


5. Gba mba nka oro re

   Ki nwi bi Samuel pe

   Ma wi, Oluwa mi

   Emi y‘o gbo Tire

   Gba mo ba si wa n'ile Re

   Ma wi tori ranse Re, ngbo. Amin

English »

Update Hymn