HYMN 636

(FE 662)1. MO layo pe Baba wa li orun 

   F'ife Re han ninu iwe li orun 

   Mo r'ohun ‘yanu ninu Bibeli 

   Ife Jesu si mi b’o ti po to.

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi 

      Jesu fe mi, Jesu fe mi 

      Mo Iayo wipe Jesu fe mi 

      Jesu fe an'emi.


2. Mo gbagbe Re, mo si sako kuro 

   Sibe o fe mi, bi mo ti nsako

   Mo fo pada s’abe apa ‘fe Re 

   Gbati mo ranti pe Jesu fe mi. 

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi...


3. B‘o je pe orin kan ni mo le ko

   Ninu ewa ni mo r‘Oba Nla ni 

   Eyi ni y’o j'orin mi tit‘aye 

   Iyanu lo je pe Jesu fe mi.

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi...


4. Jesu fe mi, mo mo pe, emi fe E 

   lfe lo mu wa lati gba mi la 

   N'ife l’O ku lori agbelebu

   O da mi loju pe Jesu fe mi. 

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi...


5. B’a bi mi lere, kini esi mi? 

   Ogo fun Jesu, eyi si daju

   Erni mimo pelu mi si gbagbo

   Lati jeri wipe Jesu fe mi. 

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi...


6. Eyi daju pe, mo ni isimi

   A bukun mi pe mo gba Jesu gbo

   A gb’okan mi la, Esu sa fun mi

   Gbati mo so fun u pe Jesu fe mi.

Egbe: Mo layo wipe Jesu fe mi 

      Jesu fe mi, Jesu fe mi 

      Mo Iayo wipe Jesu fe mi 

      Jesu fe an'emi. Amin

English »

Update Hymn