HYMN 639

(FE 665)
"Eniti o po Ii Anu ni Oluwa" - Num. 14:181. OLORUN gbogbo araiye 

   Iwo t’o pe ki mole k'o wa 

   Iwo t’o pe k'eweko hu 

   O si ri be nipa ase Re.

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi 

      gbo t’emi

      Oba awimayehun 

      gbo t'emi - 3ce

      Oba a wi‐ma-yehun.


2. Olorun t’o gbo ti Mose 

   T’a pa awon oba ko fi ka 

   Olorun t’o gbo t’Elija 

   T’o si doju t'awon ota re. 

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi...


3. Olorun t'o pe k'okun wa 

   T’omo araiye ko ri di re 

   Olorun t‘o pe k’osa wa 

   T'omo araiye ko ri di re. 

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi...


4. Olorun t’o la gan ninu 

   Baba awon alaini baba 

   Olorun t’o gbo ti Estha

   T'o si gbe leke awon ota re. 

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi...


5. Kerubu pelu Serafu

   F’ogo fun Baba loke 
  
   Fun isegun t’o nse fun wa 

   Nigbat’awon aiye fe kegan. 

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi...


6. E f’ogo fun Baba loke 

   A wa si f'ogo f’omo Re 

   A f’ogo fun Emi Mimo 

   Metalokan ni ope ye fun.

Egbe: Gbo t’emi, gbo t'emi 

      gbo t’emi

      Oba awimayehun 

      gbo t'emi - 3ce

      Oba a wi‐ma-yehun. Amin

English »

Update Hymn