HYMN 64

Tune:  Oluwa agbara fohun



1.  ’BUKUN ni f’awon mimo

     Won ti ko ‘se angeli

     Orun n’ife okan won

     Won fe lati r’Olorun

     A we abawon won nu

     Won n'idapo pelu Re

     Won dabi Oluwa won

     Ti ise ere nla fun won.


2.  Won n’josin ninu emi

     Won wole ni’bi'te Re

     Won te ba nib‘imole

     lmole Olorun tan

     Awon olokan-riro

    Ti won fe lati kekoo

    Won wa inu Oro naa

    Titi won fi gb’ohun Re.


3.  Oun ni Eleda won

     Won ba Oun nikan soro

     Lat‘ooro di asale

     Ni won nyin l'Ojo ‘sinmi

     Won di Ii mu ninu laalaa

     Won gbekele e n'nu ‘ponju

     lmole Re n tan n'nu won

     Ayida ko bori re.


4.  Oun ni won n yin l'aye won

     Won ki yoo ri iku mo

     Won yoo maa b'Oluwa gbe

     Titi won yoo fi jinde

     Won yoo sunmo Oluwa

     Pelu ara ajinde

     Pelu Baba n'nu Omo

     At’Emi, metalokan.  Amin

English »

Update Hymn