HYMN 640

t.h.C 366 8s 7s (FE 666)
Tani mo ni laiye bikose lwo1. A! KO s‘alabaro l'aiye 

   Mase ronu nitori

   Ti ko si alabaro mo 

   Jesu ju Iya on Baba.

Egbe: Tu 'ju re ka 

      Sa gbekele Olorun.


2. A! ko s’alabaro l’aiye 

   Mase beru, bi aiye 

   Ba nyi o ka ninu eru 

   Jesu yio wa pelu re.

Egbe: Ke pe Jesu

     Iwo yio segun won.


3. A! ko s‘alabaro l'aiye 

   Ma foiya b’igbi aiye

   Ba bo o mole b’okun nla 

   Iwo yio bori dandan.

Egbe: A! ma beru

     Jesu yio wa pelu re.


4. A! ko s'alabaro l’aiye 

   Ma binu b’aiye nkegan 

   T'o si nsata re nitori 

   T'iwo ko ni enikan.

Egbe: Sa gbadura 

     Ibanuje yio dayo.


5. A! ko s’alabaro l’aiye 

   Ma roju b’ebi npa o 

   Olorun to mbo era ‘le 

   On na y'o o si bo o yo.

Egbe: Gbekele mi

      Eyi l'ase Jehofa.


6. A! ko s’alabaro l‘aiye 

   Ma kanu ‘po re l'aiye 

   Olorun yio le esinsin 

   Fun malu ti ko n‘iru.

Egbe: Sa wo Jesu

      Ekun re yio si d’ayo.


7. Jesu nikan l'Alabaro 

   On l’Ore ti ki dani

   O ni Oko awon opo

   On Baba ‘laini Baba.

Egbe: Sa gbekele

     On o si ran o lowo. Amin

English »

Update Hymn