HYMN 643

t.s. 338 or SSS 874 P.M (FE 669) 
“Awa ri ile kan lati odo Olorun ile ti
a ko fi owo ko" - 2Kor.5:11. KINl y;'o Kehin aiye? 

   Kerubu pelu Serafu 

   Gege bi oko Noah 

   Kerubu pelu Serafu 

   Olorun Elijah
  
   T‘o k’awon enia re 

   L’aginju aiye ja 

   Kerubu pelu Serafu.


2. Irawo gbogbo wa ntan 

   Kerubu pelu Serafu 

   Egbe Mimo wo l‘eyi? 

   Kerubu pelu Serafu 

   Olorun Kerubu

   T’o k'awon enia re 

   L’aginju aiye ja 

   Kerubu pelu Serafu.


3. Gbo, nwon nko Halleluya! 

   Kerubu pelu Serafu

   Orin iyin s’Oba wa 

   Kerubu pelu Serafu 

   Olorun Serafu

   T’o k’awon enia re 

   L’aginju aiye ja 

   Kerubu pelu Serafu.


4. Gbo, Eda orun nkorin 

   Kerubu pelu Serafu 

   Eda aiye ko gberin 

   Kerubu pelu Serafu

   A gboju wa soke 

   S’Olorun Alaye 

   Gb’adura edun wa 

   Kerubu pelu Serafu.


5. Mimo, Mimo l'Olorun 

   Kerubu pelu Serafu 

   Olorun Metalokan 

   Kerubu pelu Serafu 

   Olorun Abraham 

   Olorun lsaaki

   Olorun Jakobu 

   Kerubu pelu Serafu.


6. Ogo f'Olorun Baba 

   Kerubu pelu Serafu 

   Ogo f'Olorun Omo, 

   Kerubu pelu Serafu 

   Ogo f'Emi Mimo 

   Metalokan lailai

   T’o degbe yi sile

   Kerubu pelu Serafu. Amin

English »

Update Hymn