HYMN 647

o.T. 264 8.7 (FE 673)
Tune: Emi ti o nji oku dide1. OLUGBALA a de loni 

   Lati wa da Majemu 

   Ran Emi Iye Re si wa 

   K’O so gbogbo wa dotun. 

Egbe: Emi Mimo sokale wa 

      Wa fi agbara Re han 

      Olugbala, Olugbala 

      Olugbala, ba wa pe.


2. Wa tun ‘baje inu wa se 

   F’ara re han wa loni 

   Ma je ki Esu ba wa pe 

   Ran Emi Re si arin wa. 

Egbe: Emi Mimo...


3. Emi Agbara sokale 

   F’owo ife yi wa ka 

   Ka simi le ileri Re 

   Ka mase siyemeji.

Egbe: Emi Mimo...


4. Ma je ki ife wa tutu 

   Larin Egbe Mimo yi 

   Ka le fa opo agutan 

   Si ‘nu agbo Mimo yi. 

Egbe: Emi Mimo...


5. Baba wa gbo tiwa loni 

   Sokale nin‘ola Re 

   Lati wa ya wa si mimo 

   K'Emi Mimo ba le wa.

Egbe: Emi Mimo...


6. E f’Ogo fun Baba l’oke 

   E f’ogo fun Omo Re 

   Ogo ni fun Emi Mimo 

   Ogo fun Metalokan.

Egbe: Emi Mimo sokale wa 

      Wa fi agbara Re han 

      Olugbala, Olugbala 

      Olugbala, ba wa pe. Amin

English »

Update Hymn