HYMN 649

L.M (FE 675)
“Nje gbogbo eniti ongbe ngbe o wa 
sibi omi" - Isa.55:11. GBOGBO eni t’ongbe ngbe wa! 

   Olorun npe gbogb’ elese

   Ra anu on ‘gbala lofe

   Ra or‘ofe ihinrere.


2. Wa s’ibi omi iye wa 

   Elese je pe ‘Eleda 
  
   Pada, asako, bo wa ‘le 

   Ofe ni ore mi fun nyin!


3. Wo Apata ti nsun jade 

   Isun ‘marale nsan fun o 

   Enyin ti eru ese npa

   E wa, l'aimo owo lowo.


4. Ko s’iparo t’e le mu wa

   E f’ini nyin gbogbo sehin 

   F'igboiya gb’ebun Olorun 

   Ni idariji n’nu Jesu. Amin

English »

Update Hymn