HYMN 660

S.492. P.M (FE 686)
“Iyawo ti Isaaki” - Gen. 25:201. IYAWO ti Isaaki gbe

   Pelu Rebeka aya re

   Olorun f'ibukun fun won 

   Gege b‘igbeyawo Adam. 

Egbe: E yo, mo si tun wipe e yo - 2ce 

     E yo, e yo, e yo nin'

     Oluwa e yo.


2. Beni ko ri fun nyin loni 

   Arakunrin, Arabinrin 

   K’ayo orun kun okan nyin 

   pelu 'bukun atoke wa.

Egbe: E yo...


3. Ninu idamu aiye yi

   Oluwa p’awon tire mo

   Fi won si abe iso Re

   Ki nwon le bo lowo ewu.

Egbe: E yo...


4. Enyin ore, at' ibatan 

   K’Oluwa gbo adura nyin 

   K'O f’ibukun fun nyin pelu 

   L'okunrin ati l'obinrin.

Egbe: E yo...


5. Enyin om'Egbe Serafu 

   Ati om’Egbe Serafu 

   Ojo ayo ni eyi je 

   K’Oluwa je ki ire kari. 

Egbe: E yo...


6. A f‘Ogo f‘Olorun baba 

   A f’Ogo f’Olorun Omo 

   A f’Ogo fun Emi Mimo 

   Metalokan Mimo lailai.

Egbe: E yo, mo si tun wipe e yo - 2ce 

     E yo, e yo, e yo nin'

     Oluwa e yo. Amin

English »

Update Hymn