HYMN 661

ISOMO LORUKO (FE 687) 
"Emi o kokiki Re, Oluwa" - PS. 30:11. EMl o kokiki Re, Oluwa 

   lwo li o da mi n'ide

   lwo ni ko je ki ota yo mi 

   Ogo ni f'oruko Re.

Egbe: lyin, Ola, Ogo ni fun O 

      Agbara ati ipa je Tire 

      Egberun ahon ko to yin O 

      A Wale, a juba Re.


2. Oluwa mi, emi kigbe pe O 

   lwo si mu mi lara da

   O yo okan mi ninu sa oku 

   O si pa mi mo l’aiye.

Egbe: lyin, Ola, Ogo...


3. Korin s'Oluwa enyin Serafu 

   K’e si dupe n‘iwa mimo Re 

   lbinu Re ki pe ju ‘seju kan 

   lye l’oju rere Re.

Egbe: lyin, Ola, Ogo...


4. Bi ekun tile pe di ale kan 

   Sibe ayo de I‘Owuro 

   Alafia si de li osan gangan 

   Mo tun di ipo mi mu.

Egbe: lyin, Ola, Ogo...


5. Nigbat‘Oluwa pa oju Re mo 

   Enu ya mi mo si kigbe

   A! kil'ere eje mi, Oluwa 

   Gba mba koja s'isa oku? 

Egbe: lyin, Ola, Ogo...


6. Bayi l'Oluwa mi gbo igbe mi 

   O si so kanu mi d‘ijo

   O bo aso ofo kuro l‘orun mi

   O f’amure ayo di mi. 

Egbe: lyin, Ola, Ogo...


7. A! Ogo mi dide si ma korin 

   Ma fi ayo korin s’oke

   Oluwa ngo fi ope fun O

   Ngo si ma yin O lailai.

Egbe: lyin, Ola, Ogo ni fun O 

      Agbara ati ipa je Tire 

      Egberun ahon ko to yin O 

      A Wale, a juba Re. Amin

English »

Update Hymn