HYMN 662

S.S. 285 (FE 688)
“Oruko mi ha wa nibe" - Dan.2:11. OLUWA ngo ko nani wura 

   ati fadaka

   Ngo mura lati d‘orun lati 

   wo ‘nu agbo

   Ninu iwe ijoba Re ti ewe re l’ewa,

   So fun mi Olugbala, Oko 

   mi ha wa n’ibe?

Egbe: Oko mi ha wa n’be 

      lara iwe funfun?

      So fun mi Olugbala 

      Oko mi ha wa n'be?


2. Oluwa ese mi po bi yanrin 

   leti okun

   Sugbon eje Olugbala o to 

   lati we mi

   Nitori ileri Re ki ye lai Oluwa, 

   B’ese nyin pon bi ododo

   Yio funfun bi sno.

Egbe: Oko mi ha wa n’be...


3. Ilu daradara ni at’ile didan Re,

   Pel’awon t’a se logo to wo 

   aso funfun

   Ohun ibi ko si mbe lati

   b’ewa re je

   Ni’b awon Angeli nso,

   Oko mi ha wa n’be. 

Egbe: Oko mi ha wa n’be 

      lara iwe funfun?

      So fun mi Olugbala 

      Oko mi ha wa n'be? Amin

English »

Update Hymn