HYMN 671

8s (FE 697)
Tune: Nigbati ldanwo yin mi ka1. EMI ko le gbagbe ojo 

   T‘iya so fun mi jeje, pe

   Bi o ba d’ominira tan 

   Mase gbagbe ojo iya. 

Egbe: Nigbati mo rohun gbogbo 

     lfe ti iya ni si mi

     Oro ife ran mi leti

     Pe ma gbagbe ojo iya.


2. Emi ko le sai ma ranti 

   Gbogbo wahala iya mi 

   To ntoju mi tosan toru 

   Ninu ebi ninu ayo.

Egbe: Nigbati mo rohun...


3. Iya wa ni onimoran 

   Baba wa ni oniranwo 

   Awon ti nse bi iya wa 

   Se won ko le jo iya wa. 

Egbe: Nigbati mo rohun...


4. Ngo se baba, ki jo baba 

   Gba ‘po de mi, ki s’onipo 

   Sole de mi, ki s’onile 

   Alagbata s’oja d’owon. 

Egbe: Nigbati mo rohun...


5. Enyin iya, e o jere omo 

   Enyin baba, e o jeun omo 

   Enikan ki o gba ‘se nyin se 

   Li agbara Edumare.

Egbe: Nigbati mo rohun gbogbo 

     lfe ti iya ni si mi

     Oro ife ran mi leti

     Pe ma gbagbe ojo iya. Amin

English »

Update Hymn