HYMN 676

t.H.C 577 6s 8s (FE 702) 
Tune: Oluwa yio pese1. IYA l'olore mi

   Ti ntoju mi Iaiye

   Ti ngbe mi pon losan

   Ti nsun ti mi loru. 

Egbe: Iya ku ise

     Nigbawo ni

     Ngo f'ope fun o 

     Fun' toju mi?


2. Eni bi ‘ya ko si 

   Ninu gbogb‘ebi mi 

   K‘Olorun da mi si 

   Ki nto iya temi. 

Egbe: Iya ku ise...


3. Baba ni jigi mi 

   Iya mi ni wura

   Ti nsun ti mi loru 

   Ti ngbe mi pon kiri. 

Egbe: Iya ku ise...


4. Bi mo l’ogbon laiye 

   O wa lowo ‘ya mi

   Bi mo si alagbon

   Ebi iya mi ni.

Egbe: Iya ku ise

     Nigbawo ni

     Ngo f'ope fun o 

     Fun' toju mi? Amin

English »

Update Hymn