HYMN 677

H.C 507 7s. 6s 
"Ti nyin ni gbogbo won, enyin ni
ti Kristi" - 1Kor.3:22,231. ORE kan mbe fun omode 

   Loke orun lohun

   Ore ti ki yipada

   T‘ife re ko le ku

   Ko dabi ore aiye

   Ti mbe lododun 

   Oruko Re bi ore

   Wo fun nigbagbogbo.


2. Isimi kan mbe f'omode 

   Loke orun lohun 

   F’awon t'o f'Olugbala 

   Ti nke ‘Abba Baba" 

   Isimi lowo yonu 

   Low’ese at’ewu 

   Nibit'awon omode

   Y'o simi titi lai.


3. lle kan mbe fun omode 

   Loke orun lohun 

   Nibiti Jesu njoba 

   lle alafia!

   Ko s'ile t'o jo laiye 

   T’a le fi sakawe 

   Ara ro lukuluku 

   Irora na dopin.


4. Ade kan mbe fun omode 

   Loke orun lohun

   Enit’o ba nwo Jesu

   Y’o ri ina ade

   Ade t'o logo julo

   Ti y'o fi fun gbogbo 

   Awon ore re laiye 

   Awon t‘o fe nihin.


5. Orin kan mbe fun omode 

   Loke orun lohun

   Orin ti ko le su ni

   B’o ti wu k‘a ko to

   Orin t’awon angeli

   Ko le ri ko titi

   Kristi ki s'Olugbala won 

   Oba l’oje fun won.


6. Ewu kan mbe fun omode 

   Loke orun lohun

   Harpu olohun didun 

   Imope isegun

   Gbogbo ebun rere yi

   L‘a ni ninu Jesu

   E wa eyin omode

   Ki nwon le je ti nyin. Amin

English »

Update Hymn