HYMN 678

ORIN ITERIBA FUN OBI
t.S.S & S. 417 (FE 703)
“Bo wo fun baba, on iya re,m ki ojo re 
ki o le pe" - Eks. 20:12
Tune: Anu Re Oluwa l’awa ntoro1. lYA t‘o ru mi fun osun mewa 

   Ti ko somi kale

   O bi mi tan, o tun pon mi kiri 

   F'odun meta toto.

Egbe: Iya, iya, iya, mo dupe 

     Ise re t’osan t'oru 

     Nijo jije, at'ijo alaije

     Iya nitori mi.


2. Gba mo s’aisan tal‘o duro ti mi 

   T'o si gbe mi mora?

   Gba mo sokun, tani re mi l'ekun 

   lya, bi ko se 'wo.

Egbe: Iya, iya, iya...


3. Nigba ewe t’emi ko le soro 

   Tani m’ohun mo fe?

   Gba mo ndagba, tani se toju mi 

   lya, iwo ha ko?

Egbe: Iya, iya, iya...


4. Ororo oyan iya ti mo yan 

   Ko le tan lara mi

   Bi mo lowo owo mi ko le ra 

   Ise re lori mi.

Egbe: Iya, iya, iya...


5. Enyin ore te ti so ya nyin nu 

   Mo ki nyin ku ile de

   Ati enyin t’iya nyin wa laiye 

   E f’ope f’Olorun.

Egbe: Iya, iya, iya...


6. Je ka mura lati huwa rere 

   Bi omo ologbon

   Ka jo Jesu ninu iwa pele 

   Ka j’omo to gboran.

Egbe: Iya, iya, iya, mo dupe 

     Ise re t’osan t'oru 

     Nijo jije, at'ijo alaije

     Iya nitori mi. Amin

English »

Update Hymn