HYMN 680

C.M.S 491 H.C 495 6s 5s (FE 705) 
“Ko ju la si Esu, on o si sa kuro 
lodo nyin” - Jak. 4:71. MASE huwa ese 

   Ma soro ‘binu 

   Omo Jesu l’e nse 

   Omo Oluwa.


2. Kristi je oninure 

   At’Eni mimo

   Be l’awon omo Re 

   Ye k’o je mimo.


3. Emi ibi kan wa 

   To nso irin re

   O si nfe dan o wo 

   Lati se ibi.


4. E mase gbo tire 

   B‘o tile soro 

   Lati ba Esu ja 

   Lati se rere.


5. Enyin ti se‘Ieri 

   Ni omo owo 

   Lati k’Esu sile 

   Ati ona re.


6. Om'ogun Krist ni nyin 

   E ko lati ba

   Ese inu nyin ja

   E ma se rere.


7. Jesu l’Oluwa nyin

   O se eni-re

   Ki enyin omo Re

   Si ma se rere. Amin

English »

Update Hymn