HYMN 687

C.M. (FE 712)
“Iwa ole, ohun buburu bi"1. WO alapon kokoro ni 

   N’nu gbogbo itanna 

   Bi o ti nfa oyin jade

   Lara ewe gbogbo!


2. W’onje didun ti o nkojo 

   Si inu ile re!

   Wo, b‘o ti se f’ara re da 

   Wo ida didan re!


3. Be l’o ye ki nma se apon 

   N'nu gbogbo ise mi

   Esu ki s’alairi ‘se kan 

   T'o buru f'ole se.


4. Ngo ma ko iwe l’akoko 

   Lat'igba ewe mi

   Ngo si mura si ise mi 

   K’oju ma ba ti mi! Amin

English »

Update Hymn