HYMN 689

H.C 177 t.S 43. P.M
"Nitorina a fi ipile re sole lori 
apata" - Matt 7:251. IPILE TI JESU Fl LE‘LE L'EYI

   Ti Baba Aladura nto,

   K’eda mase ro pe

   O ye kuro nibe, O duro le Krist‘ apata. 

Egbe: Kerubu E yo, Serafu Eyo,

     A fi pile lele lori otito - 2ce


2. Bi ara nsan egbagbeje ohun 

   Omo Jesu yio duro ti 

   K'enia ma kegan oko Noa 

   Oko refo omo Jesu la. 

Egbe: Kerubu E yo...


3. A rojo mo Stephen , a ro ‘jo mo Peter 

   A rojo mo jesu Oluwa

   A rojo mo Mose Orimolade

   K’eda k‘o kiyes’ara.

Egbe: Kerubu E yo...


4. Baba Aladura dide damure

   Lati pade awon Kerubu

   Olorun ti yin ise Re lat‘ oke wa, 

   Ade iye yio je tire. 

Egbe: Kerubu E yo...


5. B'aiye mbu Mose,

   Awon Angeli nfe

   Olorun Abraham nfe

   Awon Ogun Orun si ngbadura re, 

   Olorun Metalokan.

Egbe: Kerubu E yo, Serafu Eyo,

     A fi pile lele lori otito

     A fi pile lele lori otito. Amin

English »

Update Hymn