HYMN 690

(FE 715)
"Bakose pe Oluwa ba ko ile na"
 - Ps. 127:1
Tune: Olorun Eleda to d’egbe Serafu1. E‘GB‘ORO Oluwa l‘enu 'ranse Re

   Gbo 'bukun Oluwa fun Serubabeli, 

   Owo Serubabeli lo bere ‘le yi

   On na ni y‘o si ko d’opin.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti 

      se ’leri bukun

      A! e ku ayo, Jesu ti 

      se 'leri bukun.


2. E gb‘oro OLuwa l‘enu ‘ranse Re, 

   B’o ti wun mi lati pon nyin loju ri

   Beni Emi yio si se nyin I‘ogo 

   Aiye yio ri y'o yin mi l'ogo.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti...


3. A Sioni ma p’ohunrere ekun mo, 

   lgba awe re ti de opin re na 

   Awon omokunrin ni igboro re, 

   L'Emi yio fi se o l’ogo.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti...


4. Wura ati fadaka ki y'o won o 

   Ogo Mi y'o si ma gbe ni arin re, 

   Ao bukun f‘oril‘ede nipa re

   Wo sa gbekle Olorun re.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti...


5. Se Emi ni Alfa ati OMEGA 

   Se Emi na l’o da Orun at’ aiye 

   Emi ki yio sa fi o sile dandan 

   Emi l’Oba Awimayehun.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti...


6. Bi mo ti wa ki Emi to da aiye yi 

   Beni Mo wa titi di isisyi

   Emi l’Eni t’o se Solomon l’ogo 

   Emi yio se nyin l‘Ogo dandan.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti...


7. L’oruko Omo Mi ni mo se ‘leri 

   Oruko Ogo Mi ni Majemu nyin 

   E ki y’o pe Mi li alairi ‘dahun 

   B’orun at’aiye nreko lo.

Egbe: A! eku ayo, Jesu ti 

      se ’leri bukun

      A! e ku ayo, Jesu ti 

      se 'leri bukun. Amin

English »

Update Hymn