HYMN 692

11.9.11.9 & Ref
"Emi Oluwa Jehofa mbe lara mi"
- Isaiah 61:11. ATI mu mi l‘aginju aye yi ja

   Lori oke ati petele

   Ko si ohun kan t’o wu mi ninu re 

   A fi Jerusalemu t‘orun.

Egbe: Ojo mbo t'a o dagbere

     Fun aye pe o digbose

     Ojo mbo, ara, ojo mbo 

     Ti a o lo s'ile wa loke.


2. Mo duro, mo wo ona Jerusalem, 

   Okan mi npongbe lati de ‘be 

   Ohunkohun ti y’o ba mu ‘dena wa 

   Metalokan ba mi mu kuro.

Egbe: Ojo mbo t'a...


3. Ojojumo l’okan ese mi npada 

   Kuro lodo Jesu Oluwa

   Jowo, Jesu, f’eje mimo Re ra mi 

   F’Emi Mimo Re to mi sona. 

Egbe: Ojo mbo t'a...


4. Aye nti mi sihin, nwon nti mi sohun 

   Se, nko ni pada lodo Jesu

   Mo seleri lati ba Jesu joba

   Ileri na ko ni tase lae.

Egbe: Ojo mbo t'a...


5. A ti fi ile rere Kenan' han mi

  Ewa re ko se f'enu royin

   Ara, bawo l‘eyin o ha se de ‘be?

  Okan ti ko de ‘be padanu. 

Egbe: Ojo mbo t'a...


6. Eyin are, e ba mi yin Oluwa 

   T’O f'ona Aposteli han mi, 

   L‘ojo oni mo mo Jesu l‘Oba mi, 

   O f’Emi Mimo Re kun ‘nu mi.

Egbe: Ojo mbo t'a...


7. Jesu, jowo di mi mu titi d’opin 

   Ki nle ba O d‘opin l‘o dun ju, 

   Aleluya! e yin Jesu l’ekan si, 

   Aleluya! l’orin ikehin!. Amin

English »

Update Hymn