HYMN 694

H.C 389 D. 7s (FE 719)
“Ko si Oluwa ninu Ina na ati iji 
nla bikose ninu ohun kele 
kekere" - 1Oba 19:121. JEJE laisi ariwo

   Jeje sa ni orun nran 

   Gbat' o ba yo ni ila re, 

   Eda si le wo oju re 

   B‘o si ti ngoke pele 

   Jeje l‘agbara re npo 

   Titi y‘o fi kan tari 

   Nin’ogo t’a ko le wo.


2. Okunkun t’o n’ipa ju

   Ko wa pelu okiki 

   Osupa ati Irawo

   Ti ntan ‘mole y‘aiye ka 

   Nwon ko wa pelu iro 

   lri nla ti o nse

   Yi gbogbo aiye yi ka 

   Ko wa pelu okiki.


3. Bayi n’ise OLORUN 

   Larin EGBE MIMO yi 

   B’a ti je alailera 

   T'agbara wa ko si po 

   Sugbon ipese BABA 

   ‘Jojumo l'o nyo si wa 

   Nipa GBARA OLORUN 

   A ko ile na pari.


4. Loni yi, OLORUN wa, 

   Awa Egbe Serafu 

   Omode ati agba 

   Okunrin at’Obinrin 

   Onile at’alejo

   T’o wa fi ope fun O 

   Ninu ile Mimo yi 

   Masai tewogb’ope wa.


5. OLORUN METALOKAN 

   T’o da Egbe yi sile

   Ya ile yi si MIMO

   Nipa AGBARA nla re 

   Sokale l’ojo oni

   F’agbara wo gbogbo wa, 

   Ki gbogbo wa je TIRE 

   Laiye yi ati l’orun. Amin

English »

Update Hymn