HYMN 696

(FE 721)
“Oluwa awon omo ogun gbo
adura mi." ‐ Ps. 84:8
Tune: T’Oluwa nile at’ekun re.1. OGUN Orun, e wa ba wa yo 

   Fun ile t’a nsi loni

   Awa be O Jesu baba wa 

   Ma sai bukun wa loni.

Egbe: Yala Eru l'o nkepe O 

      Tabi ominira, Baba 

      Ko gbo n'ile yi.


2. Awa dupe lowo Re Baba 

   T’o mu ileri Re se 

   Baba se leri fun Kerubu 

   O mu se fun Serafu.

Egbe: Yala Eru...


3. Baba se ‘leri fun Abraham 

   O mu se fun Isaaki

   Baba se ‘leri fun Dafidi

   O mu se fun Solomon.

Egbe: Yala Eru...


4. Ogo ati Ola fun Baba 

   Ogo F'Omo Re pelu 

   Ogo ati ola fun Eni.

Egbe: Yala Eru l'o nkepe O 

      Tabi ominira, Baba 

      Ko gbo n'ile yi. Amin

English »

Update Hymn