HYMN 698

C.M.S 416 H.C 422 10
10.10 4 (FE 23) 
"A fi awosanma eleri pupo yi wa ka."
- Heb. 12:11. F'AWON enia Re to lo simi

   Awon ti o f’igbagbo jewo Re,

   A yin oruko Re, Olugbala, 

   Helleluya!


2. Iwo l’apata won at’odi won 

   Iwo ni Balogun won l'oju ‘ja, 

   Iwo ni imole okunkun won 

   Halleluya!


3. Je ki awon omo-ogun Re laiye, 

   Jagun nitoto b‘awon ti ‘gbani

   Ki nwon le gba ade ogo bi won

   Halleluya!


4. Idapo ibukun wo lo to yi

   Awa nja nihin, awon nyo lohun 

   Be Tire kanna l’awa at‘ awon 

   Halleluya!


5. Gbat’ ija ngbona ti ogun nle 

   A dabi eni ngborin ayo won 

   Igboiya a si de at'agbara 

   Halleluya!


6. Ojo nlo orun wa fere wo na 

   Awon ajagun toto y’o simi 

   Didun ni isimi Paradise 

   Halleluya!


7. Lehin eyi ojo ayo kan mbo 

   Awon mimo yo jinde ninu Ogo 

  Oba ogo y‘o si wa larin won 

  Halleluya!


8. Lat‘ opin ile lat’opin okun 

  Ogunlogo nro wo bode Pearli 

  Nwon nyin Baba, Omo ati Emi 

  Halleluya! Amin

English »

Update Hymn