HYMN 699

(FE 725)
"Nitori ki yio si oru nibe" - Ifi. 21:251. ILE kan mbe to dara julo 

   A le fi ‘gbagbo ri I’okere 

   Nitori Baba duro l'ona 

   Lati fi le kan fun wa nibe. 

Egbe: Kerubu, Serafu

      E ho fun ayo lojo oni - 2ce


2. Awa y’o korin l’ebute na 

   Orin didun awon t’a bukun 

   Okan wa ko ni banuje mo 

   Tori ayo ailopin wa n’be. 

Egbe: Kerubu, Serafu...


3. Baba wa Olore ni orun 

   Nikan n'iyin at’ope ye fun 

   Tori ebun ogo ife re

   Eyiti se Olugbala wa. 

Egbe: Kerubu, Serafu...


4. Tan mole Re si okunkun wa, 

   L’akoko t’egbe Serafu de

   Ki gbogbo aiye le yipada 

   Lati juba fun Kristi Oluwa.

Egbe: Kerubu, Serafu...


5. Gba t’a gbe ago erupe wo

   Ti ota ba fe se wa n’ibi 

   T’erokero ba fe gb’okan wa, 

   Ki Jehofa ko gbo ebe wa.

Egbe: Kerubu, Serafu...


6. Nigbat’ o ba d’ojo ikehin 

   Ti omo ko ni mo baba re 

   Ma je k’oju ti wa lojo na 

   Ki Metalokan tewo gba wa.

Egbe: Kerubu, Serafu

      E ho fun ayo lojo oni - 2ce Amin

English »

Update Hymn