HYMN 700

C.M.S 421.H.C 519 P.M (FE 727)
"Angeli Oluwa wipe, Lo so
gbogbo oro iye yi" - Ise. 5:201. GBO, okan mi, bi Angeli ti nkorin 

   Yika orun ati yika aiye

   E gbo bi oro orin won ti dun to

   Ti nso gbati ese ki y’o si me.

Egbe: Angeli Jesu, angel'mole 

     Nwon nkorin ayo pade ero 

     Iona.


2. B’a si ti nlo be l’a si ngbo orin won

   Wa alare, Jesu l’o ni k’e wa

   L’okunkun ni a ngbo orin didun won 

   Ohun orin won ni nfona han wa.

Egbe: Angeli Jesu...


3. Ohun Jesu ni a ngbo l’ona rere 
 
   Ohun na ndun b’agogo y’aiye ka 

   Egbegberun awon t’o gbo ni si mbo 

   Mu won w’odo Re Olugbala wa. 

Egbe: Angeli Jesu...


4. Isimi de, bi wahala tile po 

   Ile y’o mo, lehin okun aiye 

   Irin ajo pari f’awon alare

   Nwon o d’orun bi simi nikehin.

Egbe: Angeli Jesu...


5. Ma korin nso, enyin Angeli rere 

   E ma korin didun k’a ba ma gbo 

   Tit’ ao fi nu omije oju wa nu;

   Ti ao si ma yo titi lailai.

Egbe: Angeli Jesu, angel'mole 

     Nwon nkorin ayo pade ero 

     Iona. Amin

English »

Update Hymn