HYMN 701

8.7.8.7 D1. OLUWA, a gbe okan wa

   Si O n‘nu orin iyin

   A m’ore ope wa fun O 

   Pelu iho ayo nla 

   Gbogbo papa f'ewa bora 

   Awon oke nho f‘ayo 

   Oka po l’afonifoji

   Tobe ti won fi nkorin.


2. Loni, ojo ikore wa 

   Awa jewo ore Re

   Awa f’ope mu ebun wa 

   Akoso ibukun Re

   Wo l’o nfi ore-ofe bo 

   Okan awa eda Re

   Wo ti npese onje ojo 

   Fi onje orun bo wa.


3. A nfarada oru ojo 

  Laalaa a si ma su-ni 

  Sugbon nigbati oorun wo 

  Simi de fun alaare

  Se wa l’eni itwogba 

  Gbat‘ angeli ba nkore 

  K’a je alikama Kristi

  Ti On y‘o to si aba.


4. lbukun n'ile Olorun 

   Bit‘ awon mimo wa lae 

   Papa wura teju ni be 

   Odo re ndan bi Kristal 

   Orin egbe mimo t'ohun 

   Dapo mo tiwa loni 

   Bukun orin kore na po 

   Ti a o ma ko titi. Amin

English »

Update Hymn