HYMN 702

t.H.C 559. 6s. 8s (FE 729)
“E ma yo ki e si ma yo ayo nla"
- Matt. 12

1. AJODUN wa l'a nse

   Aw’ Egbe Serafu 

   Ajodun wa l‘a nse

  Aw’ Egbe Kerubu. 

Egbe: Arakunrin, Arabinrin 

     E ku odun, e ku 'yedun.


2. Kerubu t‘aiye yi

   O fere d‘igi nla

   Serefu t’aiye yi

   Ko le sai tan kiri.

Egbe: Arakunrin, Arabinrin... 


3. K‘Olorun b‘asiri

   Fun Omo Egbe wa 

   K‘enikan ma rahun 

   Lati ri onje je. 

Egbe: Arakunrin, Arabinrin... 


4. Ki esu ma ri wa

   At’eni buburu

   Aje, oso, nse lasan 

   Lor'Egbe Serafu.

Egbe: Arakunrin, Arabinrin... 


5. Emi airi nso wa

   K’a ma ri ijogbon

   Mase f'aye sile

   Lati ma gbadura. 

Egbe: Arakunrin, Arabinrin... 


6. Ohun buburu kan

   Ko ri wa gbese mo 

   Gbogb' Egbe agbaiye 

   K’a s'otito d'opin. 

Egbe: Arakunrin, Arabinrin... 


7. K'a n’ife ara wa

   K’okan wa k’o sokan 

   K’a le ri ‘bukun gba 

   ‘Bukun lopolopo.

Egbe: Arakunrin, Arabinrin 

     E ku odun, e ku 'yedun. Amin

English »

Update Hymn