HYMN 704

t. 8s 7s (FE 731)
"Iwo o pa mo li alafia" - Isaiah.26:3
Tune: Baba to da orun meje


1. ALAFIA ni f‘Egbe na,

   T'o nse ajodun loni 

   Kerubu t’oke sokale 

   Lati ba wa yo ayo na. 

Egbe: Awa njo-awa nyo 

     Ogun orun sokale - 2ce


2. Omo Egbe Kristi Mimo 

   E wa k’ajo y‘ayo na 

   K'enikeni ma ku sehin

   Gbogbo wa ni Jesu npe. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


3. Egbe Kerubu Serafu 

   At‘awon aladura 

   At‘enyin onisin-owuro 

   Jek‘a korin na soke. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


4. Egbe Mary, Egbe Martha 

   Egbe Ayaba Esther

   Egbe Dorcas gbohun soke 

   K'a jumo yo ayo na.

Egbe: Awa njo-awa nyo...


5. Orin Halle,Halleluyah 

   L‘awa yio ma ko lorun 

   Gbat‘aba ri Olugbala 

   Lor'ite Baba loke. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


6. Egbe Dafidi, Egbe Aaroni 

   Egbe F’Ogo Olorun han 

   Egbe Baba nla mejila 

   Gbe ‘da segun nyin soke.

Egbe: Awa njo-awa nyo...


7. E f'Ogo fun Baba loke

   E f’Ogo fun Omo Re

   Ogo ni fun Emi Mimo

   Ope ye Metalokan.

Egbe: Awa njo-awa nyo 

     Ogun orun sokale

     Ogun orun sokale. Amin

English »

Update Hymn