HYMN 706

(FE 733)
"E di amure yin” - Luku 12:35 
Tune: Oluwa fise ran mi Alleluya


1. AWA l'omo ogun Kristi Alleluya

  T’Oluwa gbe dide funra Re 

  Awa nsajodun loni Alleluya 

  A dupe fun ‘dasi emi wa. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun Kristi 

     Korin soke s'Oba wa

     Ope ni fun Olugbala Alleluyah

     Fun idasi wa d’ojo loni.


2. Gbogbo egbe Kaduna Alleluyah

   E f'ogo fun Baba wa l’oke 

   F’Egbe Omo-Ogun Kristi Alleluyah

   T’Oluwa gbe dide larin yin.

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


3. Esu ma gbogun titi, Alleluyah 

   Lati b’egbe Mimo yi subu 

   Sugbon Jesu gbe wa ro Alleluyah

   Ogo ni fun Baba wa loke.

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


4. Ope FOlugbala wa Alleluyah

   T‘o da wa si lati esi wa 

   Awa si ngbadura, Alleluyah 

   K‘a le se opolopo odun. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


5. Jesu Olor'egbe wa, Alleluyah

   A f‘ogo f'oruko Mimo Re 

   Jowo di wa l’amure Alleluyah

   K'a le jagun b'omogun toto. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


6. Ki gbogbo egbe ho ye Alleluyah

   K’a f’ogo fun baba wa l’oke 

   K'a f‘ogo fun Omo Re

   K’a tun f’ogo fun Emi Mimo.

Egbe: Damuso Omo-Ogun Kristi 

     Korin soke s'Oba wa

     Ope ni fun Olugbala Alleluyah

     Fun idasi wa d’ojo loni. Amin

English »

Update Hymn