HYMN 707

(FE 734)
Tune: E ti gbo orin ile wura na1. A KI nyin e ku ajodun oni 

   Enyin omo Egbe Serafu

   A dupe lowo Baba wa orun 

   T’o da wa si di oni.

Egbe: E ho iho ayo gbogbo Serafu 

     Fun ogun rere ti fun wa 

     Lat’owo Mose Orimolade 

     T'o d’Egbe Serafu s’aiye.


2. Awon olufe wa ti goke lo 

   Nwon koja s’aiya baba wa 

   Nwon mboju wo wa lati oke na 

   Lati wo b‘a ti nsise.

Egbe: E ho iho ayo...


3. Baba Aladura mura giri 

   Lati tele ona na

   Sise pelu gbogbo agbara Re 

   K‘egbe le tesiwaju.

Egbe: E ho iho ayo...


4. Eni owo ‘tun Baba Aladura 

   Ogbeni Senior Apostle

   Ati gbogbo awon Apostle 

   E gbe iwo ‘gbagbo s’oke.

Egbe: E ho iho ayo...


5. A ki nyin gbogbo enyin oloye 

   E ku ajodun oni yi

   L‘okunrin, l’obinrin

   K’a se ‘yi ka s’amodun.

Egbe: E ho iho ayo gbogbo Serafu 

     Fun ogun rere ti fun wa 

     Lat’owo Mose Orimolade 

     T'o d’Egbe Serafu s’aiye. Amin

English »

Update Hymn