HYMN 708

S.O. E.D 522 (FE 735) 
“Lojojumo Ii ao si ma yin I“ - Ps. 72:15 
Tune: Edumare Jah Jehovah1. BABA Orun wa gb’ope wa 

   Fun ajodun wa oni yi 

   Fun idasi at’abo Re

   To nfun wa lojojumo.

Egbe: Jehofa Jire

      Ran ibukun Re si wa 

      K’awa le se 'fe Re d’opin 

      Ko wa de Paradise.


2. Olugbala wa gb’ope wa 

   T’isegun t’o nse fun wa 

   Gbat’esu nfe bi wa subu 

   Ti a si nri ‘ranwo Re.

Egbe: Jehofa Jire...


3. Kerubu ati Serafu 

   E jek’a yin Baba wa
 
   Ti ko f’emi adaba Re 

   Fun eranko igbe je.

Egbe: Jehofa Jire...


4. Jehofa Shammah mbe fun wa 

   T’o ran Maikaeli si wa

   Fun ‘segun wa l‘ona gbogbo 

   Iyin fun Metalokan.

Egbe: Jehofa Jire...


5. Olupese wa y’o pese 

   Pese ‘se rere fun wa 

   Awon agan y’o bimo 

   Enit’ o bi a tunla.

Egbe: Jehofa Jire...


6. Wa pelu Egbe Idale 

   Kerubu on Serafu

   Pese fun won l‘ona gbogbo 

   Baba wa ba won ‘segun.

Egbe: Jehofa Jire...


7. A mbebe f'awon eda Re 

   T'o wa ni gbogbo aiye 

   K'a ronu pa iwa wa da 

   K’a le ye ‘bugbe orun.

Egbe: Jehofa Jire...


8. Gbogbo enyin ero mimo 

   Ti Egbe Aladura

   E se ran nyin l‘okansoso 

   Gege bi Metalokan.

Egbe: Jehofa Jire...


9. Orin Halle, Halleluyah, 

   Ni awa y’o ko l’orun 

   Nigbat‘ a ba de ‘te Baba 

   N’ile isura orun.

Egbe: Jehofa Jire

      Ran ibukun Re si wa 

      K’awa le se 'fe Re d’opin 

      Ko wa de Paradise. Amin

English »

Update Hymn